Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrin àwọn ìgbèkùn ní etí òdò Kébárì, àwọn ọ̀run sí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

2. Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn Ọba Jehóákímù—

3. ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Ísíkẹ́lì, ọmọ Búsì wá, létí odò Kébárì ni ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

4. Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùukùu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárin iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,

5. àti láàrin iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (4) wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn,

6. ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.

7. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán.

8. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́,

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 1