Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 9:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Fún wọn, Olúwa!Kí ni ìwọ yóò fún wọn?Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́àti ọyàn gbígbẹ.

15. “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní GílígálìMo kórìírà wọn níbẹ̀,Nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé miÈmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.

16. Éfúráímù ti rẹ̀ dànùGbogbo rẹ̀ sì ti rọ,kò sì so èso,Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

17. Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀nítorí pé wọn kò gbọ́ràn sí i;wọn yóò sì di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

Ka pipe ipin Hósíà 9