Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 7:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọnÈmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀runNígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀Èmi nà wọ́n bí ìjọ ènìyàn wọn ti gbọ́

13. Ègbé ní fún wọn,nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!Ìparun wà lórí wọn,nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!Èmi yóò rà wọ́n padà.Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi

14. Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn.Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnìṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.

15. Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,ṣíbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.

Ka pipe ipin Hósíà 7