Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 6:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jíní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípòkí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀

3. Ẹ jẹ́ kí a mọ OlúwaẸ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́.Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,Yóò jáde;Yóò tọ̀ wá wá bí òjòbí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4. “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù?Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà?Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

5. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu miÌdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín

6. Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ;àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

7. Bí i Ádámù, wọ́n da májẹ̀múwọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi níbẹ̀.

8. Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburútí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

Ka pipe ipin Hósíà 6