Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 6:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwaó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹṣùgbọ́n yóò mú wa lára dáÓ ti pa wá láraṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.

2. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jíní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípòkí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀

3. Ẹ jẹ́ kí a mọ OlúwaẸ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́.Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,Yóò jáde;Yóò tọ̀ wá wá bí òjòbí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4. “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù?Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà?Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

5. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu miÌdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín

Ka pipe ipin Hósíà 6