Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì wí fún mi pé, “Lọ, fi ìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀ padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn ti fẹ́ ẹ, tí òun sì tún jẹ́ alágbèrè. Fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe fẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tẹ́lé àwọn òrìṣà tí ó sì fẹ́ràn oúnjẹ tí àwọn aláìkọlà yà sọ́tọ̀.”

2. Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀dógún (15) àti Ómírì kan àti lẹ́tíkì báálì kan.

3. Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú ù rẹ.”

4. Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láì ní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́ láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.

Ka pipe ipin Hósíà 3