Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 2:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,Èmi yóò fi àfonífojì Ákórì ṣe ilẹ̀kùn ìrètí fún un.Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Éjíbítì

16. “Yóò si ṣe ní ọjọ́ náàÌwọ yóò pè mí ní ‘Ọkọ mi’;Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ni Olúwa wí.

17. Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Báálì kúrò lẹ́nu rẹ̀;ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Báálì pè mọ́

18. Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀múfún wọn àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti ẹyẹ ojú ọ̀run àtiàwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́Ọrun, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náàkí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.

19. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé.Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àtiòtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.

20. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní ìsòtítọ́ìwọ yóò sì mọ Olúwa

21. “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà”ni Olúwa wí.“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùnàwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;

22. Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,wáìnì tuntun àti òróró lóhùnGbogbo wọn ó sì dá Jésírẹ́lì lóhùn.

Ka pipe ipin Hósíà 2