Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 2:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àánú.’

2. “Ẹ bá ìyáa yín wí, ẹ bá a wí,nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀àti àìsòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.

3. Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòòhòÈmi yóò sì gbé e kalẹ̀ lá ìwọṣọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a bí i.Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀Èmi yóò sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́.

4. Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́

5. Ìyá wọn jẹ́ aláìsòótọ́ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi,tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,aṣọ oríṣìíríṣìí, òróró àti ohun mímu’ lẹ́yìn.

Ka pipe ipin Hósíà 2