Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 11:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù?Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lìBáwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà?Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù?Ọkàn mi yípadà nínú miÀánú mi sì ru sókè

9. Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹtàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoroNítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyànẸni mímọ́ láàrin yín,Èmi kò ni i wa nínú ìbínú

10. Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìúnNígbà tó bá búàwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn.

11. Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rùbi i ẹyẹ láti Éjíbítìbi i àdàbà láti ÁsíríàÈmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Hósíà 11