Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tó gbaléó ń sọ èṣo fún ara rẹ̀Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí ibí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rereÓ bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.

2. Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹbáyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

3. Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọbanítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwaṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,kí ni yóò se fún wa?”

4. Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,wọ́n ṣe ìbúra èké,wọ́n da májẹ̀mú:báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,bi i koríko májèlé láàrin oko tí a ro.

Ka pipe ipin Hósíà 10