Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 10:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tó gbaléó ń sọ èṣo fún ara rẹ̀Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí ibí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rereÓ bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.

2. Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹbáyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

3. Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọbanítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwaṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,kí ni yóò se fún wa?”

4. Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,wọ́n ṣe ìbúra èké,wọ́n da májẹ̀mú:báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,bi i koríko májèlé láàrin oko tí a ro.

5. Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samáríàbẹ̀rù nítorí ere màlúù tó wà ní Bẹti-Áfẹ́nìÀwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lóríbẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,nítorí ogo rẹ̀ nítorí o tí lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

6. A ó gbé lọ sí Ásíríàgẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńláa ó dójú ti Éfúráímù;oju yóò ti Ísírẹ́lì nítorí ere òrìṣà rẹ̀

7. Bí igi tó léfòó lórí omi niSamaríà àti àwọn ọba rẹ yóò ṣàn lọ.

8. Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà buburú ni a o parun—Ẹ̀sẹ̀ Ísírẹ́lì ni.Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”

9. “Láti ìgbà Gíbíà, ni ó ti sẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lììwọ sì tún wà níbẹ̀.Njẹ́ ogun kò léẹ̀yin aṣebi ni Gíbíà bá bí?

10. Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;Orílẹ̀ èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojú kọ wọnLáti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11. Éfúráímù jẹ́ ọmọ màlúù tí atí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkàlórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà nièmi ó dí ẹru wúwo léÈmi yóò mú kí a gun Éfúráímù bí ẹṣinJúdà yóò tú ilẹ̀,Jákọ́bù yóò sì fọ́ ogúlùtu rẹ̀

Ka pipe ipin Hósíà 10