Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hágáì 2:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Báyìí ni Olúwa alágbára wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:

12. Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan Búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

13. Nígbà náà ni Hágáì wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nipa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọkan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”

14. Nígbà náà ni Hágáì dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olukuluku iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rúbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.

15. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsí bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹ́ḿpìlì Olúwa.

16. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìlé ogún, mẹ́wàá péré ni. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni.

17. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdú àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jà; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

18. ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹ́sàn-án, yìí kí ẹ kíyèsí, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì Olúwa lé lẹ̀, ròó dáradára:

19. Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránátè, àti igi ólífì kò ì tíì so èso kankan.“ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún-un yin.’ ”

20. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hágáì wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé:

21. “Sọ fún Sérúbábélì baálẹ̀ Júdà pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.

Ka pipe ipin Hágáì 2