Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 3:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀;Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá,níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ;ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

6. Ó dúró, ó sì mi ayé;ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrìa sì tú àwọn òkè-ńlá ayérayé ká,àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

7. Mo rí àgọ́ Kúṣánì nínú ìpọ́njúàti àwọn ibùgbé Mídíanì nínú ìrora.

8. Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa?Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò síṣàn bí?Ìbínú rẹ ha wá sórí òkuntí ìwọ fi ń gún ẹṣin,àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlá rẹ?

9. Ìwọ kò bo ọrun rẹ,o sì pè fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọfàìwọ sì pín ayé níyà pẹ̀lú odò.

10. Àwọn òkè-ńlá ri ọ wọn ṣì wárìrìàgbàrá òjò ń ṣàn án kọjá lọ;ibú ń ké ramúramùó sì gbé irú omi sókè.

11. Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ibùgbé wọn,pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

12. Ní ìrúnú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

13. Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là;Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,fifi ìpìlẹ̀ hàn títí dé ọrùn

14. pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹnígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀jáde láti tú wá ká:ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ talákà run ní kọ̀kọ̀.

15. Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn òkun já,O tẹ òkun mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀,ìwọ fi àwọn ẹsin rẹ̀ rin òkun já,ó sì mu omi ńlá jáde okiki omi ńlá

16. Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì,mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmúláti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

Ka pipe ipin Hábákúkù 3