Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 1:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Bábílónì dìde,àwọn aláìláàánú àti onínú fùfù ènìyàntí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé jáláti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe ti wọn.

7. Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,Yóò máa ti inú wọn jáde.

8. Ẹ̀ṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,wọ́n ṣì gbóná jú ìkókó àṣálẹ́ lọàwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;àwọn yóò sì wá láti ọ̀nà jínjìn réré,wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun

9. Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipáìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;wọn sì ko ìgbékùn jọ bí i yanrìn.

10. Wọn ó si máa fí àwọn ọba ṣẹ̀ṣínwọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìnín;Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á

11. Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,yóò sì rékọjá, yóò siṣẹ̀ ní kika agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”

12. Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ mi, àwa kì yóò kú Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí

13. Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;ìwọ kò le gbà ìwà ìkànítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láàyè?Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń paẹni tí i ṣe olododo ju wọn lọ run?

14. Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú òkun,bí àwọn ẹ̀dá inú òkun tí wọn ko ni alákòóso

15. Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn ṣókèó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n-ńlá rẹ̀;nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Hábákúkù 1