Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 1:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran tí wòlíì Hábákúkù rí.

2. Olúwa, emì yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?

3. Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéÈéṣe tí ìwọ sì fààyè gba ìwà ìkà?Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.

4. Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,ìdájọ́ òdodo kò sì borí.Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà

5. “Ẹ wo ìnú àwọn aláìkọlà, ki ẹ sí wòye,Kí ìyàlẹnu kí o sí ṣe yin gidigidiNítorí tí èmi yóò ṣe ohun kan ni òwúrọ̀ ọjọ́ ọ yíntí ẹ̀yin kì yóò sì gbàgbọ́bí o tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un yin.

6. Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Bábílónì dìde,àwọn aláìláàánú àti onínú fùfù ènìyàntí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé jáláti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe ti wọn.

7. Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,Yóò máa ti inú wọn jáde.

8. Ẹ̀ṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,wọ́n ṣì gbóná jú ìkókó àṣálẹ́ lọàwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;àwọn yóò sì wá láti ọ̀nà jínjìn réré,wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun

9. Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipáìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;wọn sì ko ìgbékùn jọ bí i yanrìn.

10. Wọn ó si máa fí àwọn ọba ṣẹ̀ṣínwọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìnín;Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á

11. Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,yóò sì rékọjá, yóò siṣẹ̀ ní kika agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”

12. Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ mi, àwa kì yóò kú Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí

Ka pipe ipin Hábákúkù 1