Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 9:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítà sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hámánì ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí oun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.

26. (Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Púrímù, láti ara ọ̀rọ̀ Púrì). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn,

27. Àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbàá gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn.

28. A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kía sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Púrímù wọ̀nyí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrin irú àwọn ọmọ wọn.

29. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ayaba, ọmọbìnrin Ábíháílì, pẹ̀lú Módékáì aráa Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Púrímù yìí múlẹ̀.

30. Módékáì sì kọ ìwé ránsẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbéríko mẹ́tadínláàdóje (127) ní ilé ọba Ṣéríṣésì ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀

31. Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ọ Púrímù yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Módékáì àti Ẹ́sítà ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò ààwẹ̀ àti ẹkún un wọn.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 9