Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 9:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Módékáì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ṣéríṣésì, tí ó wà ní tòòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré,

21. Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Ádárì ní ọdọọdún

22. Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àṣè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.

23. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Módékáì ti kọ̀wé sí wọn.

24. Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítà sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hámánì ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí oun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.

26. (Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Púrímù, láti ara ọ̀rọ̀ Púrì). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn,

27. Àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbàá gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn.

28. A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kía sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Púrímù wọ̀nyí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrin irú àwọn ọmọ wọn.

29. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ayaba, ọmọbìnrin Ábíháílì, pẹ̀lú Módékáì aráa Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Púrímù yìí múlẹ̀.

30. Módékáì sì kọ ìwé ránsẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbéríko mẹ́tadínláàdóje (127) ní ilé ọba Ṣéríṣésì ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 9