Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 7:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Ẹ́sítà ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaà mi, n ó fi fún ọ.”

3. Nígbà náà ni ayaba Ẹ́sítà dáhùn, “Bí èmi bá rí ojú reree rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláà ńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀míì mi-èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́-èyí ni ìbéèrè mi.

4. Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá ti lẹ̀ tàwá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹbá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”

5. Ọba Ṣéríṣésì sì bi Ésítà ayaba léèrè pé, “ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?”

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 7