Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 6:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Módékáì tí sọ àṣírí Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n ń gbérò láti pa ọba Ṣérísésì.

3. Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí?”Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tíì sí ohun tí a ṣe fún-un.”

4. Ọba wí pé, “Taa ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un.

5. Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hámánì ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”

6. Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ọ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”Nísinsìnyìí Hámánì sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Taa ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?”

7. Nítorí náà ó dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,

8. jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba má a ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí.

9. Jẹ́ kí a fí aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn-ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn má a kéde níwájúu rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”

10. Ọba pàṣẹ fún Hámánì pé, “Lọ lẹ́ṣẹ̀ kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Módékáì araa Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.”

11. Bẹ́ẹ̀ ni Hámánì ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Módékáì, Módékáì sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájúu rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”

12. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Módékáì padà sí ẹnu ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hámánì ṣáré lọ ilé, ó sì bo oríi rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́,

13. Ó sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ síi fún Ṣérésì ìyàwóo rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀.Àwọn olùbádámọ̀ràn an rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún-un pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Módékáì ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubúu rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!”

14. Bí wọ́n ṣe ń báa sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hámánì lójú láti lọ sí ibi àṣè tí Ẹ́sítà ti pèsè.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 6