Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 4:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Módékáì gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kunra, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe ṣókè ó sì sunkún kíkorò.

2. Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láàyè láti wọ ibẹ̀.

3. Ní gbogbo ìgbèríko tí ikú àti àṣẹ ọba dé, ọ̀fọ̀ ǹlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú ààwẹ̀, ẹkún àti ìpohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ninú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra.

4. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Ẹ́sítà wá, wọ́n sọ nípa Módékáì fún-un, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ síi kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n.

5. Nígbà náà ni Ẹ́sítà pe Hátakì, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún-un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Módékáì àti ohun tí ó ṣe é.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Hátakì jáde lọ bá Módékáì ní ìta gbangba ìlú niwájú ẹnu ọ̀nà ọba.

7. Módékáì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún-un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hámánì ti ṣe ipinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù.

8. Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀.

9. Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ.

10. Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì,

11. “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láì jẹ́ pé a ránsẹ́ pèé (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá a góòlùu rẹ̀ síi kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”

12. Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Ẹ́sítà fún Módékáì,

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 4