Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 3:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ṣérísésì dá Hámánì ọmọ Hámádátà, ará a Ágágì lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tó kù lọ.

2. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hámánì, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Modékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún-un.

3. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé, “È éṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.”

4. Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún-un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hámánì nípa rẹ̀ láti wòó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Módékáì ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

5. Nígbà tí Hámánì ríi pé Módékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú.

6. Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Módékáì jẹ́, ó kẹ́gàn àti pa Módékáì nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hámánì ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Módékáì run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ṣérísésì.

7. Ní ọdún kejìlá ọba Ṣérísésì, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù nísánì, wọ́n da Púrì (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hámánì láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Ádárì.

8. Nígbà náà ni Hámánì sọ fún ọba Ṣérísésì pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fánká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tó kù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 3