Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 2:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ní alẹ́ ni yóò lọ ṣíbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣáásígásì ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyààfi tí inú ọba bá dùn síi, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin.

15. Nígbà tí ó kan Ẹ́sítà (ọmọbìnrin tí Módékáì gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Ábíháílì) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò bèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hégáì, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Ẹ́sítà sì rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i.

16. A mú Ésítà lọ síwájú ọba Ṣéríṣésì ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹ́wàá, tí ó jẹ́ oṣù Tébétì, ní ọdún kéje ìjọba rẹ̀.

17. Ésítà sì wu ọba ju àwọn obìnrin tó kù lọ, Ó sì rí ojú rere àti oore ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúndíá tó kù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Fásítì.

18. Ọba sì se àsè ńlá, àsè Ésítà, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbéríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó.

19. Nígbà tí àwọn wúndíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọbà.

20. Ṣùgbọ́n Ẹ́sítà pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́gẹ́gẹ́ bí Módékáì ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tèlé àṣẹ tí Módékáì fún-un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Módékáì.

21. Ní àsìkò tí Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba, Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Sérísésì.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 2