Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 2:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ṣérísésì ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Fásítì àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀.

2. Nígbà naà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kòì mọ ọkùnrin rí fún ọba.

3. Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hégáì, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára.

4. Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Fásítì.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

5. Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ọmọ Jáárì, ọmọ Símù, ọmọ Kúsì, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,

6. Ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ́mù, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jéóhákímù ọba Júdà.

7. Módékáì ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hádásà, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní bàbá bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Ẹ́sítà, ó dára ó sì lẹ́wà, Módékáì mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ti kú.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 2