Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 1:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Fásítì gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ṣérísésì tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”

16. Mémúkánì sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Fásítì ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan Ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba Ṣérísésì.

17. Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obínrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójúu wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ṣérísésì pàṣẹ̀ pé kí á mú ayaba Fásítì wá ṣíwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.

18. Ní ọjọ́ yìí gan-an ni àwọn ọlọ́lá obinrin Páṣíà àti ti Médíánì tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.

19. “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Pásíà àti Médíánì, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Fásítì kí ó má ṣe wá ṣíwájú ọba Ṣérísésì. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó ṣàn jù ú lọ.

20. Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”

21. Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Mémúkánì ṣé sọ.

22. Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbéríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ọ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkálùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé e rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 1