Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 1:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Fásítì kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidgidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.

13. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,

14. àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Káríṣénà, Ṣétarì, Ádímátà, Tárísísì, Mérésì, Márísénà àtí Mémúkánì, àwọn ọlọ́lá méje ti Páṣíà àti Médíà tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.

15. Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Fásítì gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ṣérísésì tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”

16. Mémúkánì sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Fásítì ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan Ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba Ṣérísésì.

17. Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obínrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójúu wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ṣérísésì pàṣẹ̀ pé kí á mú ayaba Fásítì wá ṣíwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.

18. Ní ọjọ́ yìí gan-an ni àwọn ọlọ́lá obinrin Páṣíà àti ti Médíánì tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.

19. “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Pásíà àti Médíánì, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Fásítì kí ó má ṣe wá ṣíwájú ọba Ṣérísésì. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó ṣàn jù ú lọ.

20. Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”

21. Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Mémúkánì ṣé sọ.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 1