Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 6:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.

17. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

18. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè.

19. Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá.

20. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Léfì pa ọ̀dọ́ àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.

21. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

22. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ Búrẹ́dì tí kò ní Yíìsìtì pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Ásíríà padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 6