Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 4:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.

4. Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹṢùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.

5. Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòsì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú.

6. Ìjìyà àwọn ènìyàn mitóbi ju ti Sódómù lọ,tí a sí nípò ní òjijìláì sí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

7. Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì,wọ́n sì funfun ju wàrà lọlára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,ìrísí wọn dàbí sáfírè.

8. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí wọ́n dúdú ju èédú;wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.Ara wọn hun mọ́ egungun;ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

9. Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sànju àwọn tí ìyàn pa;tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfòfún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

10. Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánúni wọ́n ṣe ọmọ wọntí ó di oúnjẹ fún wọnnígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

11. Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.Ó da iná ní Síónìtí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,tàbí àwọn ènìyàn ayé,wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọodi ìlú Jérúsálẹ́mù.

13. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíìàti àìṣedédé àwọn olórí àlùfáà,tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodosílẹ̀ láàrin rẹ̀.

14. Nísinsìnyí wọ́n ń rìn kiri ní òpópóbí ọkùnrin tí ó fọ́jú.Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́ntí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 4