Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 9:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mósè kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Fáráò.

9. Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.”

10. Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Fáráò. Mósè sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.

11. Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mósè nítorí oówò ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Éjíbítì.

12. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Fáráò le, kò sì gbọ́ ti Mósè àti Árónì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mósè.

13. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Fáráò lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sin mí,

14. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò rán ìdààmú ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.

15. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọ lù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ohun búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe dá ọ sí, kí èmi kí ó lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a bá à lè gbọ́ òkìkí orúkọ mi ní gbogbo ayé.

17. Ṣíbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.

18. Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Éjíbítì láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.

Ka pipe ipin Ékísódù 9