Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 9:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọ lù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ohun búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe dá ọ sí, kí èmi kí ó lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a bá à lè gbọ́ òkìkí orúkọ mi ní gbogbo ayé.

17. Ṣíbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.

18. Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Éjíbítì láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.

19. Pàṣẹ nísin yìí láti kó ẹran-ọ̀sìn yin àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”

20. Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Fáráò yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.

21. Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ Olúwa sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá.

22. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”

23. Nígbà tí Mósè gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bù sí orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Éjíbítì;

24. Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bù sí orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì buru jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Éjíbítì ti di orílẹ̀ èdè.

25. Jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.

26. Ilẹ̀ Gósénì ni ibi ti àwọn Ísírẹ́lì wà nikan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

27. Nígbà náà ni Fáráò pe Mósè àti Árónì sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìsòdodo.

28. Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”

29. Mósè dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúró ní àárin ilú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísàn àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 9