Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 8:17-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí.

18. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé. Kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn.

19. Àwọn onídán sì sọ fún Fáráò pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Fáráò sì yigbì, kò sì fetí sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

20. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Fáráò lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn mi.

21. Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Éjíbítì ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú.

22. “ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, èmi yóò ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí.

23. Èmi yóò pààlà sáàárin àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”

24. Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Fáráò àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.

25. Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”

26. Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá?

27. A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”

28. Nígbà náà ni Fáráò wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú ihà, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”

29. Mósè dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, awọn esinsin yóò fi Fáráò, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánílójú wa pé Fáráò kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”

30. Nígbà náà ni Mósè kúrò ni ọ̀dọ̀ Fáráò, ó sì gbàdúrà sí Olúwa;

Ka pipe ipin Ékísódù 8