Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 7:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Éjíbítì sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Fáráò sì yigbì ṣíbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

23. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀.

24. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Náílì láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà.

25. Ọjọ́ Méje sì kọjá ti Olúwa ti lu Odò Náílì

Ka pipe ipin Ékísódù 7