Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 5:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”

10. Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Fáráò sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.

11. Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ”

12. Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Éjíbítì láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.

13. Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti se fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.”

14. Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ yàn lára ọmọ Ísírẹ́lì ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”

15. Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ Fáráò lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ ti fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí?

16. Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

17. Fáráò sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ niyín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ni ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí Olúwa.’

18. Nísínsìnyìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”

19. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”

20. Ní ìgbà tí wọ́n kúró ni ọ̀dọ̀ Fáráò wọ́n rí Mósè àti Árónì tí ó dúró láti pàdé wọn.

21. Wọn sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Fáráò àti àwọn òsìṣẹ̀ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni ìdà láti fi pa wá.”

22. Mósè padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi?

23. Láti ìgbà ti mo ti tọ Fáráò lọ láti bá a sọ̀rọ̀ ni orúkọ rẹ ni ó ti mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ rárá.”

Ka pipe ipin Ékísódù 5