Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 39:33-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Wọ́n sì mú tabánákù náà tọ Mósè wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀sọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34. ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji àsọ títa;

35. àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

36. tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;

37. ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;

38. pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

39. Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀;

40. aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá; ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà; gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;

41. aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

42. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páṣẹ fún Mósè.

43. Mósè bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà ṣẹ. Nítorí náà Mósè sì bùkún fún wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 39