Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 37:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹ̀ka mẹ́fà ní ó jáde láti ìhà ọ̀pá fìtílà náà mẹ́ta ní ìhà àkọ́kọ́ àti mẹ́ta ní ìhà èkejì.

19. Kọ́ọ̀bù mẹ́ta ni a se bí ìtànná alímóndì pẹ̀lú ìrùdí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà.

20. Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀:

21. Ìrùdí kan níṣàlẹ̀ ẹ̀ka méjì jáde lará ọ̀pá fìtílà náà, ìrùdí kejì níṣàlẹ̀ èkejì, àti ìrùdí kẹ́ta níṣàlẹ̀ ìrùdí ìkẹta-ẹ̀ka mẹ́fà lò wà lára gbogbo rẹ̀.

22. Ìrùdí náà àti ẹ̀ka wọn jẹ́ bákan náà, ó lù ú jáde ní kìkì wúrà.

23. Ó se fìtílà méje rẹ̀, pẹ̀lú àlùmágàjí àti àwo rẹ̀ kìkì wúrà ni.

24. Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara talẹ́ńtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.

25. Igi kaṣíá ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìdajì mítà, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìdajì mítà àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà kan-ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà.

26. Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká.

27. Ó se òrùka wúrà méjì sí ìṣàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní ọ̀kánkán ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e.

28. Ó ṣe òpó igi kaṣíá, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà.

29. Ó sì tún ṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí-iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

Ka pipe ipin Ékísódù 37