Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 34:14-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ẹ má se sin ọlọ́rùn mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ òjòwú, Ọlọ́run owú ni.

15. “Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.

16. Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò se àgbérè tọ òrìsà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà se bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

17. “Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère kankan

18. “Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú osù Ábíbù, nítorí ní osù náà ni ẹ jáde láti Éjíbítì wá.

19. “Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i se, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn.

20. Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́ àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà.“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá ṣíwájú mi ní ọwọ́ òfo.

21. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kó dà ní àkókò ìfúrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi.

22. “Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso àlìkámà àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún.

23. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa, Ọlọ́run Isirẹli.

24. Èmi yóò lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

25. “Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì se jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀.

26. “Mú èyí tí ó dára nínú àkọ́so èso ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.“Má ṣe ṣe ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.”

27. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”

28. Mósè wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láì jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.

Ka pipe ipin Ékísódù 34