Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 32:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Éjíbítì, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.

8. Wọ́n ti yára láti yípadà kúrò nínú ohun ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹ̀gbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rúbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Ísíirẹ́lì wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.’ ”

9. Olúwa wí fún Mósè pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn.

10. Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbòná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.”

11. Ṣùgbọ́n Mósè kígbe fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, è é ṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Éjíbítì wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?

12. È é ṣe tí àwọn ará Éjíbítì yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́ mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ.

13. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

14. Nígbà náà ni Olúwa yí ọkàn padà, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.

15. Mósè sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú okuta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.

16. Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín-in sára àwọn òkúta wàláà náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 32