Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 32:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìsà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mósè ẹni tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá àwa kò mọ ohun tí ó sẹlẹ̀ sí i.’

24. Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”

25. Mósè rí i pé àwọn ènìyàn náà kòṣe e ṣàkóso àti pé Árónì ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrin àwọn ọ̀ta tí ó dìde sí wọn.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Léfì sì péjọ yí i ká.

27. Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Isirẹ́lì, wí pé: ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládúgbò rẹ.’ ”

28. Àwọn ará Léfì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kù tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ènìyàn.

29. Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”

30. Ní ọjọ́ kejì Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè se ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31. Bẹ́ẹ̀ ni Mósè padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìsà wúrà fún ara wọn.

32. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa oruko mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”

Ka pipe ipin Ékísódù 32