Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 32:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nígbà tí Mósè dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì ju pálí ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ ní ìṣàlẹ̀ òkè náà.

20. Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu ún,

21. Mósè sọ fún Árónì pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”

22. Árónì dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú Olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó.

23. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìsà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mósè ẹni tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá àwa kò mọ ohun tí ó sẹlẹ̀ sí i.’

24. Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”

25. Mósè rí i pé àwọn ènìyàn náà kòṣe e ṣàkóso àti pé Árónì ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrin àwọn ọ̀ta tí ó dìde sí wọn.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Léfì sì péjọ yí i ká.

Ka pipe ipin Ékísódù 32