Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 31:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí,

9. pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀

10. àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,

11. òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Kí wọ́n se wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe paṣẹ fún ọ.”

12. Olúwa wí fún Mósè pé,

13. “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ̀yín gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrin èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

14. “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.

15. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ.

16. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò se máa pa ọjọ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíràn tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mu títí láé.

17. Yóò jẹ́ àmí láàrin èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

18. Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ ṣíṣọ fún Mósè lórí òkè Ṣínáì, ó fún-un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, okuta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

Ka pipe ipin Ékísódù 31