Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 31:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Olúwa wí fún Mósè pé,

13. “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ̀yín gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrin èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

14. “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.

15. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ.

16. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò se máa pa ọjọ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíràn tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mu títí láé.

17. Yóò jẹ́ àmí láàrin èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

18. Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ ṣíṣọ fún Mósè lórí òkè Ṣínáì, ó fún-un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, okuta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

Ka pipe ipin Ékísódù 31