Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 30:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kaṣíà kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀.

2. Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

3. Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì se wúrà gbà á yíká.

4. Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní ọ̀kánkán ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fí gbé e.

5. Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kaṣíà, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà.

6. Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ títa, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.

7. “Árónì yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fítìlá náà ṣe.

8. Òun yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ni ń bọ̀.

9. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú Àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀.

10. Árónì yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Óun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀. Mímọ́ jùlọ ni sí Olúwa.”

11. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mósè pé,

12. “Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn kì yóò sún mọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn.

13. Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì sékéli (gíráámù mẹ́fà), gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gérà. Ìdajì sékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.

14. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa.

15. Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì sékélì lọ, àwọn talákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì sékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti se ètùtù fún ọkàn yín.

16. Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì fi lé lẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”

17. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mósè pé,

18. “Ìwọ yóò si ṣe agbada idẹ kan, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 30