Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 3:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Lọ, kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sí sọ fún wọn, ‘Olúwa Ọlọ́run Jákọ́bù; yọ sí mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojúwò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Íjíbítì.

17. Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ilẹ̀ Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì; ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin.’

18. “Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò fetí sílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbààgbà yóò jọ tọ ọba Éjíbítì lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Hébérù ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’

19. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Éjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀.

20. Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárin wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

21. “Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Éjíbítì pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo.

22. Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun Sílífà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Éjíbítì.”

Ka pipe ipin Ékísódù 3