Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 29:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.

16. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wọ́n-ọn sí pẹpẹ ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

17. Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn.

18. Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná se sí Olúwa ni.

19. “Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.

20. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sí pẹpẹ lórí àti ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

21. Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n-ọn sára Árónì àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.

22. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́).

23. Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.

24. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

25. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa.

26. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Árónì, ìwọ yóò si fín-in ni ẹbọ fínfín níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

27. “Ìwọ yóò sì yà igẹ̀ ẹbọ fínfìn náà sí mímọ́, àti ìtan ẹbọ àgbésọ-sókè, tí pa fi tí a sì gbésọ-sókè nínú àgbò ìyàsímímọ̀ náà, àní nínú èyí tíí ṣe Árónì àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.

28. Èyí ni yóò sì máa se ìpín ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à-gbé-sọ-sókè ni ẹbọ tí yóò sìṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa se sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

29. “Asọ mímọ́ Árónì yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́.

Ka pipe ipin Ékísódù 29