Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 28:35-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.

36. “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fífín èdìdì àmì pé: ‘Mímọ́ sí Olúwa.’

37. Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà.

38. Kí ó wà níwájú orí Árónì, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Árónì nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.

39. “Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Iwọ yóò sì fi ṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè.

40. Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Árónì, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

41. Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Árónì arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlú, ìwọ óta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì Sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa se iṣe àlùfáà.

Ka pipe ipin Ékísódù 28