Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:8-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo aṣọ títa mọ̀kánlà náà gbọdọ̀ jẹ́ déédé-ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀wọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

9. Aṣọ títa márùn ún ni kí ó papọ̀ mọ́ ara wọn sí apá kan àti mẹ́fà tókù sí apá ọ̀tọ̀. Yí aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà.

10. Ṣe àádọ́ta ọ̀jábó sí etí òpin aṣọ títa ni apá kan, kí o sì tún ṣe é sí etí òpin aṣọ títa sí apá kejì.

11. Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi ṣo àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan.

12. Àti ìyóòkù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13. Asọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.

14. Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀.

15. “Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa.

16. Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀.

17. Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.

18. Ṣe ogún (20) pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà

19. Ṣe ogójì (40) ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.

20. Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó ṣíbẹ̀

21. àti ogójì (40) ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan.

22. Ṣe pákó mẹ́fà sí ni ìhà opin ìwọ̀ òòrùn àgọ́ náà,

23. kí o sì se pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn.

Ka pipe ipin Ékísódù 26