Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:35-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fitílà sí ọ̀kánkán rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36. “Fún ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elésèé àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe.

37. Ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, kí o sì bò ó pẹ̀lú òpó igi kasíà márùn ún pẹ̀lú wúrà. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà márùn ún fún wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 26