Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àti ìyóòkù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13. Asọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.

14. Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀.

15. “Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa.

16. Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀.

17. Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.

18. Ṣe ogún (20) pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà

19. Ṣe ogójì (40) ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.

20. Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó ṣíbẹ̀

Ka pipe ipin Ékísódù 26