Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣe àádọ́ta ọ̀jábó sí etí òpin aṣọ títa ni apá kan, kí o sì tún ṣe é sí etí òpin aṣọ títa sí apá kejì.

11. Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi ṣo àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan.

12. Àti ìyóòkù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13. Asọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.

14. Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀.

15. “Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa.

16. Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀.

17. Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.

18. Ṣe ogún (20) pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà

Ka pipe ipin Ékísódù 26