Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 23:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo.

7. Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbi olódodo ènìyàn, nítorí èmi kò ní dá ẹlẹ́bí láre.

8. “Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń fọ àwọn tó ríran lójú, a sì yí ọ̀rọ̀ olódodo po.

9. “Ìwọ kò gbọdọ pọ́n àlejò kan lójú sa ti mọ inú àlejò, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10. “Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni talákà láàrin yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà-àjàrà rẹ àti ọgbà Olífì rẹ.

12. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

13. “Ẹ máa sọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má se pe orúkọ òrìṣà, kí a má se gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.

14. “Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò se àjọ̀dún fún mi nínú ọdún.

15. “Ṣe àjọ̀dún àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Ábíbù, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

16. “Ṣe àjọ̀dún ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.“Ṣe àjọ̀dún àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó irè oko rẹ jọ tan.

17. “Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Ọlọ́run.

18. “Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti búrẹ́di tó ní ìwúkàrà.“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.

19. “Mú èso àkọ́so ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.“Ìwọ kò gbọdọ̀ fi omi ọmú ìyá ewúrẹ́ bọ ọmọ ewúrẹ́.

20. “Kíyèsí èmi rán ańgẹ́lì kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.

Ka pipe ipin Ékísódù 23