Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 23:27-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. “Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀ta rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ.

28. Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hífì, Kénánì àti Hítì kúrò ni ọ̀nà rẹ.

29. Ṣùgbọ́n, èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan soso, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀ jù fún ọ.

30. Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní.

31. “Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí òkun pupa títí dé òkun àwọn ara Fílístínì, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Éfúrétì: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.

32. Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn.

33. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹkùn fun ọ nítóòtó.”

Ka pipe ipin Ékísódù 23